In this video, you have Yorùbá version of the Nigerian National Anthem and Pledge.
Teach yourself and your children.
Èyí ni orin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ẹ̀jẹ́ ní èdè Yorùbá. This is the Yorùbá version of the Nigerian National Anthem and Pledge.
ẸṢẸ̀ KÍNNÍ / VERSE 1
Dìde ẹ̀yin ará
Wá ká jẹ́ ìpè Nàìjíríà
K’á fìfẹ́ sin ‘lẹwa
Pẹ̀l’ókun àt’igbàgbọ́
Kí ṣẹ́ àwọn akọni wa,
kó máse já s’ásaán
K’á sìn-ín t’ọkàn tara
Ilẹ̀ tolóminira, àlàáfíà sọ́dọ̀ kan
Ilẹ̀ t’ómìnira, àt’àlàáfíà
Sọ d’ọ̀kan.
ẸṢẸ̀ KEJÌ / VERSE 2
Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá
Tọ́ ipa ọ̀nà wa
F’ọ̀nà han aṣáájú
K’ọ́dọ̀ọ́ wá m’ọ̀títọ́
K’ódodo àt’ìfẹ́ pọ̀ sí i
K’áyé wọn jẹ́ pípé
Sọ wọ́n d’eni gíga
K’álàfíà òun ẹ̀tọ́ lé
Jọba ní ‘lẹ̀ wá.
Ẹ̀JẸ́ / PLEDGE
Mo ṣe ìlérí fún Orílẹ̀-Èdè mi Nàìjíríà,
Láti jẹ́ olódodo, ẹnití ó ṣeé f’ọkàn tán
Àti olótìtọ́ ènìyàn
Láti sìn-ín pẹ̀lú gbogbo agbára mi,
Láti sa ipá mi gbogbo fún ìṣọ̀kan rẹ̀
Àti láti gbé e ga fún iyì àti ògo rẹ̀.
Kí Ọlọ́run ràn mí l’ọ́wọ́.
Translated by Adebayo Faleti
Á jú ṣe o!
431 Comments